Yoruba

Pẹ̀lú bí ìgbésẹ̀ láti mú àyípadà dé bá ńkan ọ̀sìn nílẹ̀ yí, ìjọba àpapọ̀ ti ní kí ibùdó tí wọ́n yo ti ma kẹ́ran jẹ̀, tí wọ́n yà sọ́tọ̀, kó gbérasọ, nípinlẹ̀ mọ́kàndínlógún láriwá ilẹ̀ yí, tófimọ́ ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ àti Ògùn lẹ́kùn ìwọ̀ orun gúsù ilẹ̀ yí.

Nígbà tón sọ̀rọ̀ nílu Abuja, lásìkò ìpàdé ẹlekẹrin lé lógójì, àjọ tón rísí ẹ̀ka ọ̀gbìn, àti ìdàgbàsókè ìgbèríko, alákoso fọ́rọ̀ ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókò ẹsẹ̀kuku, ọ̀gbẹ́ni Sambo Nanono, jk kó di mímọ̀ pé ìpínlẹ̀ méjìlélógún àti olúlu ilẹ̀ yí ló ti forúkọ sílẹ̀ fún ètò ọ̀hún.

Ó ní ẹ̀ka kan ni Dutch ti ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti bẹ̀rẹ̀ ìsí àkọ́kọ́ isẹ́ àkànse ọ̀hún nípinlẹ̀ Nasarawa.

Alákoso Nanono, tẹnumọ́ pé, tí wọ́n bá parí gbogbo isẹ́ ohun, yo fòpin sí ìjà lárin àwọn àgbẹ̀ àti darandaran.

Bákanà ni yo jẹ ànjàní láti mọ dunjun sisin ẹran nílànà ìgbàlódé fún àwọn tón kó ẹran jẹ̀.

Ó sọ síwájú pé yo fàyègba àyíká tó rọrùn fáwọn olùdókowò láti dókowò lẹ́ka ọ̀hún.

Olukayọde Banjọ

Yoruba

Àrẹ Muhammade Buhari ti sọ pé àmúgbòrò yo de bá ìgbáyé gbádùn àwọn èyàn nílẹ̀ Nàijírìa, bẹ̀rẹ̀ nípa ìpèsè ètò àbò tó múnádóko.

Nílu Maiduguri, l’afin Shehu ti Borno, ni àrẹ ti sọ̀rọ̀ ìdánilójú yi .

Àrẹ ẹni tó ń se àbẹ̀wò ẹnu isẹ́ ọlọ́jọ́ kan sípinlẹ̀ Borno, ló ti kọ́kọ́ se ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú okọ̀ ológun tó wà lágbègbè ọ̀hún.

Óní ìpinu òun láti sin àwọn èyàn orílẹ̀èdè yí, ló wà tatara ifẹ̀ tí wọ́n fihàn sí, bẹ lótún gbóríyìn fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno lórí akitiyan rẹ̀ láti mú ìdàgbàsókè bá ìpínlẹ̀ náà láiwo ìpèníjà lórí àbò tí wọ́n ńlà kọjá.

Nínú ọ̀rọ̀ Shehu tílù Borno, àlhájì Abubakar El-kanemi, dúpẹ́ lọ́wọ́ àrẹ lórí idahun sí ìbere àwọn èyàn ìpínlẹ̀ náà, pẹ̀lú àtọ́kasí pé ètò àbò tin rẹsẹ̀ walẹ̀ sí nípinlẹ̀ ọ̀hún.

Ọlọlade Afọnja

News Yoruba

Lara akitiyan lati se koriya fawon odo, nidi lilowo sidagbasoke awujo, Ajo Olutaniji araalu sojuse eni, NOA, eka tipinle Oyo ti se agbekale eto apero olojo kan nilu Ibadan.

Ipade apero ohun lawon egbe odo, awon odo asinrulu atawon lajo-lajo peju si, eyi to fojusun siseto, iro lagbara fawon odo, ati gbigbaradi fun ipo adari lojo iwaju.

Ninu oro re, Alaga egbe awon odo nile Nigeria, Arabinrin Adebobola Agbeja ati ajafeto awon omode, Arabinrin Ibukunoluwa Otesile to awon odo lati ma fi rawon jin pelu imo ti yoo mu agbaga ba awujo

Bakanna, Olubanidamoran Pataki si Gomina Seyi Makinde foro abo, Ogbeni Fatai Owoseni ro awon odo lati samulo ipade ohun fi mu amuyi pada re b aero won nidi kikopa tooye si idagbasoke awujo.

Saaju ninu oro ikini kaabo re, Oludari ajo NOA, nipinle Oyo, Ogbeni Moshood Olaleye gba awon odo niyanju lati dehin nidi awon iwa aito bi, gbigbe ati lilo egbogi oloro, ifipabanilopo and jagidi-jagan dipo bee, kiwon samulo ipa won lori ohun tootoo ti yoo mu won lami laka laaye.

kehinde/Idogbe