Yoruba

Ìjọba Apapọ̀ Ti Gbé Orùkọ́ Ipínlẹ̀ Mọ́kànlélógún Jáde Ti Wọ́n Yo Ni Ibùdó Iselọ́jọ̀ Fún Kíkó Eran Jẹ̀

Pẹ̀lú bí ìgbésẹ̀ láti mú àyípadà dé bá ńkan ọ̀sìn nílẹ̀ yí, ìjọba àpapọ̀ ti ní kí ibùdó tí wọ́n yo ti ma kẹ́ran jẹ̀, tí wọ́n yà sọ́tọ̀, kó gbérasọ, nípinlẹ̀ mọ́kàndínlógún láriwá ilẹ̀ yí, tófimọ́ ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ àti Ògùn lẹ́kùn ìwọ̀ orun gúsù ilẹ̀ yí.

Nígbà tón sọ̀rọ̀ nílu Abuja, lásìkò ìpàdé ẹlekẹrin lé lógójì, àjọ tón rísí ẹ̀ka ọ̀gbìn, àti ìdàgbàsókè ìgbèríko, alákoso fọ́rọ̀ ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókò ẹsẹ̀kuku, ọ̀gbẹ́ni Sambo Nanono, jk kó di mímọ̀ pé ìpínlẹ̀ méjìlélógún àti olúlu ilẹ̀ yí ló ti forúkọ sílẹ̀ fún ètò ọ̀hún.

Ó ní ẹ̀ka kan ni Dutch ti ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti bẹ̀rẹ̀ ìsí àkọ́kọ́ isẹ́ àkànse ọ̀hún nípinlẹ̀ Nasarawa.

Alákoso Nanono, tẹnumọ́ pé, tí wọ́n bá parí gbogbo isẹ́ ohun, yo fòpin sí ìjà lárin àwọn àgbẹ̀ àti darandaran.

Bákanà ni yo jẹ ànjàní láti mọ dunjun sisin ẹran nílànà ìgbàlódé fún àwọn tón kó ẹran jẹ̀.

Ó sọ síwájú pé yo fàyègba àyíká tó rọrùn fáwọn olùdókowò láti dókowò lẹ́ka ọ̀hún.

Olukayọde Banjọ

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *