News

Ijoba ipinle Ogun ti gbe awon ile mejilelogbon to wa ni Isheri nijoba ibile Ifo nipinle naa tipa, nitori pe won tapa si oniruru ofin to romo ile kiko.

Alakoso to wa fun eto ile ati idagbasoke igberiko, Ogbeni Olatunji Odunlami, lo soro yi di mimo lasiko to n baa won akoroyin soro nilu Abeokuta, to kasi pe opo ninu awon ile naa ni won ko gba ase lati ko.

Ogbeni Odunlami tenumo pe gbigba ase lati bere ile kiko ki se on to ye keeyan fi fale tabi mu sere, o tokasi pe isejoba to wa lode nipinle Ogun ni o fe sise ri daju pe abo to peye wa nipinle ohun, kawon eeyan le dokowo layika to rorun.

Alakoso naa wa gba awon to nile niyanju lati yago fun titapa si ofin ijoba.

Amugbalegbe Pataki si Gomina lori ato ilu ati idagbasoke igberiko, Ogbeni Tunde Ohegbewesa, naa bere atilehin awon to ni ile, ki won le fese abo to peye layika fun awon eeyan ipinle Ogun mule.

Folarin/Okareh/Afonja

Yoruba

Ìjọba  ìpínlẹ̀ Ògùn ti kéde pé, wọn yóò lé èyíkèyí àwọn akẹ́kọọ tó bá domi àláfìa ìkẹ́kọ́ọ̀ rú, láwọn ilé-ìwé gbogbo tó ń bẹ nípinlẹ̀ náà kúrò nílè wé.

Alákoso fétò ẹ̀kọ́ ìmọ̀ sáyẹ̀nsì àtìmọ̀ ẹ́rọ nípinlẹ̀ Ògùn, ọ̀jọ̀gbọ́n Abayọmi Arigbabu ló sísọ lójú ọ̀rs yíì nílu Abẹokuta lákokò tón báwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí báwọn akẹ́kọọ kan nílé-ìwé girama tójẹ́ tìjọba, se ;n diya jẹ, àwọn olùkọ́ wọn nítorípé wọ́n báwọn wí.

Ó fi kálèyé rẹ̀ pé, ìjọba kòní fàayè gba ìwà àilẹ́kọ àti àiníbawí èyí tíwọ́n loit gogo sára àwọn akẹ́kọ́ọ̀ kan, ó wá sèlérí pé, ilé isẹ́ rẹ̀ yóò wankan se si èyí tó wáyé náà, tí yóò sì sèwádi ohun tó sokùnfà irúfẹ́ ìwà tíkò tọ́ ọ̀hún.

Ọjọgbọn Arigbabu gba àwọn olùkọ́ tọ́rọ̀kàn níyànjú láti yan ìwà rere tí se ẹ̀sọ́ ènìyàn láàye, bẹ́ẹ̀ ló sì tún ké sáwọn òbí náà, láti lọ máà fi ohunkohun tó bá ń bíwọn nínú nípa olùkọ́ kan, tó ọ̀gá àgbà irúfẹ́ ilé-ìwé bẹ́ẹ̀ létí, fún ìgbésẹ̀ tó bá yẹ lórí rẹ̀, lái mu ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn.

Folakemi Wojuade

Yoruba

Ijoba Ipinle Ogun ti kesi awon asoju egbe osise to wa nipinle naa pe ki won pada senu ifikunlukun pelu Ijoba lati fi wa ojutu si ibeere won.

Ninu atejade ninu Abeokuta ni akowe Ijoba Ipinle naa Ogbeni Tokunbo Talabi ti soro di mimo pea won asoju egbe osise lo kuro nibi iforowero naa patapata ti won si lo kede igbese ati bere iyanselodi olose kan.

Ogbeni Talabi tenumo pe igbese yi ko bojumu to, ati pe Ijoba to wa lode lo jogun gbese owo to to billion metadinlaadofa leyi tii se owo ati pese inkan amayederun.

Akowe Ijoba Ipinle Ogun tun kede erongba Ijoba Gomina Abiodun lori amuse liana owo osun to kere julo fun gbogbo elekajeka osise bere lati osu kokanla odun yi.

Babatunde 

Yoruba

Ijoba Ipinle Ogun ti sewele ofin to room konle gbele lopin ose nipinle naa.

Gomina Dapo Abiodun lo kede yi lasoko ton so igbese tijoba ti gbe lati fopin si itankale arun Covid-19 nipinle ohun.

Gomina naa salaye pe oun gbe igbese yi leyin opolopo ijiroro pelu awon torokan, pelu atokasi pe ipinu lati kese kuro lori ofin konileogbele lopin ose lonise pelu bi won se ti si ibudo ijosin pada.

Ogbeni Abiodun sope ofin tonise pelu keyan maju ogun lo ninu apejopo ni osimule.

O safikun pe liana lati si awon ibi igbafe, ere idaraya, sobu agerun ta, ati ibi ti won ti se eso irun ni won nsise le lori.

Ololade Afonja