Yoruba

Aare Ile Igbimo Asofin agba, Ogbeni Ahmed Lawan ti sekilo fawon Gomina nipinle atawon miran to di ipo ase mu, tilu dibo yan, lati yago fun piparapo bere fun atunto nile yi.

Ilu Abuja ni Ogbeni Lawan ti soro yo, ro si ni ko ye ko je iru awon eeyan tilu dibo yan, ni won yoo ba nidi irufe iwayi.

Gegebi otiwi, oni ki won se atunto lawon ipinle kowa won, ki won to ma bere fun ti ijoba apapo.

Aare ile asofin tenumo pe, awon asaju yi lo ye ki won ri daju pe gbogbo onikojiko darapo mo eto isejoba ti yo le faye gba eni to ba ni nkan to le se lati mu kile yi goke agba lese laini idiwo.

O tokasi pe gbogbo eeyan nile yi lo ye ki won parapo laifi tie sin, asa tabi egbe oselu teni kookan di mu se, lati wojutu si gbogbo ipenija to n koju ile yi lapapo.

Aare ile asofin, Ogbeni Lawan, wa kesi gbogbo awon tilu dibo yan yika ema ijoba meteeta lati yago fun ikunsinu to le da togbodiyan sile tabil eyi to le fa ipinya.

Afonja

Yoruba

Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ilẹ̀ yíì, ọ̀mọ̀wé Ahmed Lawan sọpé ilé ti setán láti sàtúngbéyẹ̀wò òfin tó síse pẹ̀lú ilégbe ìjọba àpapọ̀ láti mú ìdúró réè bá ẹ̀ka náà kíì ìfẹsẹ̀múlẹ̀ tílẹ̀lé ìlànà yíì fáwọn ilésẹ́ aládani jẹ́ títẹ̀lé sansan.

Ọmọwe Lawan sọ èyí lásìkò tíì olùdarí ilésẹ́ tó ńrísí ilégbe ìjọba àpapọ̀, ọ̀gbẹ́ni Gbenga Ashafa, léwájú àwọn ikọ̀ kan réè sàbẹ̀wò sí adarí ilé asòfin àgbà lọ́fìsì rẹ̀.

Gẹ́bẹ́ bí adarí ilé sewípé, àtúnse ìlànà ilégbe ọhun jẹ́ ìgbésẹ̀ tó ti yẹ́ẹ̀ kówáyé lọ́jọ́ tótipẹ́,.

Ọmọwe Lawan wá rọ àwọn adarí lẹ́ka ohun lórí ìgbésẹ̀ tíwọ́n ńgùnlé láti jẹ́ mú isẹ́ méjì papọ̀.

Net/Elizabeth Idogbe

Yoruba

Igbimo tekoto Ile Igbimo Asofin Agba Foro Isuna yoo bere igbese lori owona fodun 2020 sodun 2023 bere lojoru ose to nbo.

Atejade kan talga Igbimo Tekoto Ile Fun Oro Isuna, Ogbeni Solomon Adeola fisita sope agbarijopo Igbimo Tekoto Ile Igbimo Asofin Agba naa ton ri soro isuna ati eto gbogbo ti pin awon iwe ipe sawon ile ise, eka ati lajolajo toje ti ijoba lati wa farahan niwaju ile kiwon leso ero tiwon lori igbese naa.

Asofin Adeola wa tenumo idi tofisepataki kiwon sise lori biwon yoo se jeki owo ori agba epo robi wa ni ogoji dollar tiwon yoo file maa pese epo robi toto milioni kan o le die agba epo robi lojojumo.

Ololade Afonja