Yoruba

Ileese olopa ile yi ti tepele mo igbiyanju lori ipese aabo to peye fawon ileese ati olori jori ton se amulo opopona marose Ibadan silu Eko.

Igbakeji oga agba ileese, Olopa ile yi fun ekun keji, Ogbeni Johnson Kokumo lo fowo oro yi soya nilu Abeokuta lasiko abewo lenu ise to se si Gomina ipinle Ogun, omooba Dapo Abiodun.

Ogbeni Kokumo salaye wi pe ekun keji ileese olopa ile yi lo n se kokari ipinle Ogun ati ipinlle Eko leyi to je ki won maa gbero eto igbogun tiwa odaran alajumo se, Pataki julo lagbegbe Kara lopopona marose.

Nigba to n femi imoore han sijoba to wa lode nipinle Ogun fun ipese inkan iranwo fun leese olopa, Ogbeni Kokumo salaye wipe ileese re ti pari eto gbogbo nidi ati mu eto aabo gbopon lagbegbe naa.

Ninu oro re, Gomina Dapo Abiodun salaye wi pe ileese Oloogun naa ti seleri atileyin fun joba ohun nidi atimaa dode awon ajinigbe, o war o ileese olopa pe ki won se ise po pelu ideese oloogun lati se aseyori.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Lasiko ijoko ile, lati mu ki agbega de ba ilese ohun, ati aba ofin lori idasile ileeko ti won yo ti maa ko nipa ile olopa, Ogbeni Yusuf Gagdi tenumo ipinnu ile ise olopa atawon eka to se koko.

Gegebi asofin naa tiwi, gbigbe liana kale ti yio risi asiko ti IGP yoo lo ninu ofiisi ni saa kan ni yio mu mu ki ileese olopa tunbo sise daganjia si, nibamu pelu liana igbanisise, idanileko loorekoore to fimo titi owo naa gba fun awon ise to se koko.

Afonja

Yoruba

Saaju eto idibo Gomina ti yoo waye lola nipinle Edo, oga agba yanyan funleese Olopa ile yi, Ogbeni Mohammed Adamu ti pase pe ki opin ba igbokegbode oko nipinle naa lati oru oni titi di aago mefa irole ola.

Ninu atejade ti agbenuso ileese Olopa ile yi DCP Frank Mba fi sita ni Oga Agba ileese Olopa ti soo di mimo wipe igbese naa sepataki nitori ati dena lilo bibo pelu inkan ija oloro ati egboogi olowo, ati lati ko awon janduku oselu lapapo

Oga Agba ileese Olopa war o gbogbo eeyan Ipinle naa pe ki won tu yaayaa jade lojo idibo lati dibo fun eni to wu won, o tun salaye wipe ileese Olopa ati gbogbo awon eleto aabo to ku lo ti wa ni igbaradi lona ati je kalaafia joba.

O sekilo wipe awon agbofinro ko ni faaye gba jagidijagan Kankan tabi igbese jiji apoti ibo gbe pelu tabo-rabo, to fi mo sisoro kobakungbe sira eni pelu gbogbo iwa yoowu to ba ke pagidina ijagara eto idibo naa.

Babatunde