News Yoruba

Won ti gbawon Musulumi niyanju lati tubo maa gbe igbeaye Alafia pel’awon elomiin.

Eyi lo jeyo ninu atejade kan, talaga egbe awon musulumi to je akosemose oniroyin nile yi, MMPN, Eka tipinle Oyo, Alhaji Ridwan Fasasi fisita fayeye ojo ibi anobi fun todun yi.

O salaye pe, okan Pataki lara eko to jise nla Muhammad fikoni ni sise daada sara ile re, nitori pe, awon ni won dijo sunmo rawon julo, eyi to le mu igbeaye Alafia gbile.

Alhaji Fasasi ko sai tokasi pe, ise tojise nla Mohammad ran somo niyan ni Islam, eyi to tumosi Alafia, to is je pe ko si esin yoowu to faaye awon iwa tabi ise kan, tolodi si ifesemule Alafia ati idurosinsin re latodo enikeni.

Fasasi/Wojuade

Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ ti kéde ọjọ́ ìsẹ́gun Tuesday àti ọjọ́rú Wednesday ọ̀sẹ̀ tónbọ̀ gẹ́gẹ́bí ìsinmi lẹ́nu isẹ́ láti le sọdún iléyá tọdún yi.

Ọrọ yí lówà nínú àtẹ̀jáde èyí tí àkọ̀wé àgbà sí alákoso lórí ọ̀rọ̀ abẹ́lé, ọ̀mọ̀wé Shuaib Belgore fisíta, pẹ̀lú àtọ́kasí pé alákoso fọ́rọ̀ abẹ́lé Rauf Arẹgbẹsọla ló kéde ohun, lórúkọ ìjọba àpapọ̀ nílu Abuja.

Ọgbẹni Arẹgbẹsọla wá, kí gbogbo àwọn Mùsùlùmí òdodo àti àwọn èyàn nílẹ̀ Nàijírìa, nílé àti lókè òkun kú ọdún Eil-el-kabir.

Alákoso wá rọ gbogbo àwọn èyàn nílẹ̀ yí láti tẹ̀lé gbogbo ìlànà tó rọ̀mọ́ dídènà ìtànkákẹ̀ àrùn covid-19 papa wiwọ ibomu, fífọ ọwọ́ lórekére àti yíyàgò fún ìfin kínra.

Ololade Afọnja  

Yoruba

Ajo eleto ilera agbaye, WHO, ti gbe ipolongo lori a ti dena arun Korona laarin awon omo ileyi, gba odo awon olori esin lo ni ipinle Ogun.

Ilaniloye lori ati dena arun naa ni won se fun awon Lemomu ati Alufa ninu Mosalasi Ilu Egba, to wa ni Kobiti, nilu Abeokuta.

Akoroyin wa j’abo iroyin wipe awon akopa ninu ipolongo ilaniloye naa ni won kojopo lati awon Mosalasi  ati legbelegbe ijo Musulumi kaakiri ijoba ibile to wa nipinle Ogun.

Wale Oluokun