News Yoruba

Àwọn èèkàn ọmọ ilẹ̀ yíì, àwọn olósèlú àtàwọn tó dipò àsẹ mú nílẹ̀ yíì, nílu ìbàdàn ti kórajọpọ̀ sí ibùdó ìkírun tó wà ládugbò Agodi láti kí ìrun ọdún iléyá fún tọdún yíì.

Ibùdó ìkírun náà làwọn olùjọ́sìn péjú sí, pẹ̀lú onírunru asọ lọrùn wọn, èyí tó ń sàfihàn ayẹyẹ ọdún iléyá.

Lára àwọn èèyàn náà latirí igbékejì Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ẹ̀rọ Rauf Ọlaniyan, igbákejì alága ẹgbẹ́ òsèlú PDP, ọ̀gbẹ́ni Taofeek Arapaja, olórí òsìsẹ́ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, Àlhájà Ọlọlade Agboola àtàwọn èèyàn min-in.

Nínú wáási rẹ́ tó fún ìrun Eid tọdún yíì, Imam àgbà fún ilẹ̀ ìbàdàn, Àlhájì Abdulganiyu Agbọ́ tọmọ kekere tó sàpèjúwe ayẹyẹ ọdún iléyá fún tọdún yíì gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ fifi ara ẹnijìn tó sì wá gba àwọn Mùsùlùmí níyànjú láti máà dúpẹ́ fún Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà.

Net/Wojuade

Yoruba

Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti kí gbogbo àwọn mùsùlùmí nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ kú oríre ọjọ́ ìbí òjísẹ́ ńlá Muhammad.

 Nínú àtẹ̀jáde èyí tí akọ̀wé àgbà lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn sí Gómìnà, ọ̀gbẹ́ni Taiwo Adisa fisíta, Gómìnà rọ àwọn Mùsùlùmí láti gbé ẹ̀wù ìfẹ́, àláfìa, ìfiraẹnijì wọ̀.

Gómìnà Makinde tún fi àsìkò ọdún yi láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo àwọn tọ́rọkàn láti dákun dábọ̀ gba àláfìa láye pẹ̀lú àtọ́kasí pé isẹ́ gbogbo èyà ní láti ridájú pé ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ túnbọ̀ dárasi.

 Bákanà, ẹgbẹ́ àwọn Mùsùlùmí tó jẹ́ òsìsẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ nílẹ̀ Nàijírìa, MMPN, ẹ̀ka ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ rọ àwọn asíwájú nílẹ̀ yí láti wo àwòkọ́se ìhùwàsí òjísẹ́ ńlá Muhammad nínú èyí anu síse , níní ẹ̀rí ìfẹ́, wiwanisọkan jugbogboẹlọ ọ̀kan nínú ìdáwọ́lé wọn.

 Nínú àtẹ̀jáde èyí tí alága ẹgbẹ́ ohun Àlhájì Ridwan Fasasi fis;ita nílu’ bàdàn ni ọ̀rọ̀ yi ti jẹyọ, pẹ̀lú àtọ́kasí pé, híhùwà òdodo ni gbogbogbà, ló wà lára o n tólè gbé orílẹ̀èdè yí jòkè àgbà, dọ́gba pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ tóti gòkè àgbà lágbayé.

Adebisi/Afọnja