News Yoruba

Àwọn Mùsùlùmí jékèjádò orílẹ̀èdè ti tújáde lọ́pọ̀ yanturu fún ìrun yídì ayẹyẹ ọdún iléyá tón lọ lọ́wọ́.

Àwọn èèkàn ọmọ ilẹ̀ yíì, àwọn olósèlú àtàwọn tó dipò àsẹ mú nílẹ̀ yíì, nílu ìbàdàn ti kórajọpọ̀ sí ibùdó ìkírun tó wà ládugbò Agodi láti kí ìrun ọdún iléyá fún tọdún yíì.

Ibùdó ìkírun náà làwọn olùjọ́sìn péjú sí, pẹ̀lú onírunru asọ lọrùn wọn, èyí tó ń sàfihàn ayẹyẹ ọdún iléyá.

Lára àwọn èèyàn náà latirí igbékejì Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ẹ̀rọ Rauf Ọlaniyan, igbákejì alága ẹgbẹ́ òsèlú PDP, ọ̀gbẹ́ni Taofeek Arapaja, olórí òsìsẹ́ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, Àlhájà Ọlọlade Agboola àtàwọn èèyàn min-in.

Nínú wáási rẹ́ tó fún ìrun Eid tọdún yíì, Imam àgbà fún ilẹ̀ ìbàdàn, Àlhájì Abdulganiyu Agbọ́ tọmọ kekere tó sàpèjúwe ayẹyẹ ọdún iléyá fún tọdún yíì gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ fifi ara ẹnijìn tó sì wá gba àwọn Mùsùlùmí níyànjú láti máà dúpẹ́ fún Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà.

Net/Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *