Yoruba

Ile igbimo asofin ipinle Oyo ti roe ka alase nipinle Oyo lori titejade ohun ifilede gbogbo aba tile igbimo ohun ti so dofin.

Ipe naa lo tele oro lori Pataki tetejade to fi mo fifelede awon ofin ohun ti asofin to n soju ekun idibo Ariwa Ogbomosho, Arabinrin Olawumi Oladeji gbe siwaju ile.

Nigba to n sagbekale aba ohun, Arabinrin Oladeji wa kominu pe opo awon aba tile igbimo naa ti so dofin lo sin je ajeji sawon araalu, teleyi ko si se leyin aise agbejade re tiru fe nkan be si n pagidina itele ofin naa.

Nigba to n gboriyin fun awon ile ise igbounsafefe lori ipa won lori agbejade ise gbogbo tile igbimo asofin nse, asofin ohun sope omi si n ba lamu lori tita awon eya ji lawujo.

Ewe nigba to n ka afenuko ile, adari ile igbimo asofin ipinle Oyo, Ogbeni Adebo Ogundoyin waro eka alase lati ri daju pe won seto gbogbo lori atejade awon ofin naa.

Kehinde/ Olaopa

Yoruba

Omo ile asofin ipinle Oyo kan ton soju ekun gusu Ibarapa ati aringbun gun, Ogbeni Peter Oyedokun nfe ki amugboro deba, awon nkan amayederun ati owonaa toto fun Ile Eko, Olukoni Agba tipinle Oyo, to wa ni Lanlate.          

Nigba ton gbe aba ti kale, Ogbeni Ojedokun, sope lati igba ti won ti se idasile ile ekoni yi ni ko ti ni awon nkan amayederun toto fun eto ikoni.

O fi aidunu han lori bi, ile ekoni ati yara ikowe pamosi, eyi ti gomina teleri Alao Akala, gbe fawon agbesese l’odun 2006, se ti di apati bayi.

Ninu oro eyi ti adari ile so, Ogbeni Adebo Ogundoyin nfe ki agbasese fara han niwaju ile, lati dahun awon ibere ori on to sele si millionu lona ogun naira eyi ti won gba lowo ijoba ipinle lati pari ise akanse naa.

Ile asofin tun pa lase pe ki ilewe naa, tun pese, iwe lori bi won se nawoo larin odun marun, ki won le mo ipo pato ti ile eko naa wa.

Ninu orormiran ewe, ile igbimo asofin gbe iko eleni marun dide ti yo sewadi esun isekupa omode kunrin kan l’agbebge Mokola ti won fi kan iko Amotekun. Mosọpe Kehinde/Ọlọlade Afọnja

Yoruba

Gẹ́gẹ́bí ara ọ̀nà láti fòpin sí ètò àbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ ìbàràpá, adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin ti gbé alùpùpù mẹdogun tuntun fáwọn ẹ̀sọ́ alábo tójẹ́ ọmọbíbí ilẹ̀ ìbàràpá.

Nígbà tón gbé àwọn alùpùpù náà fáwọn olórí agbègbè àti àwọn asíwájú ẹ̀sọ́ alábo lágbègbè nílesẹ́ ọlọ́pa tówà nílu Èrúwà, ọ̀gbẹ́ni Ogundoyin sọpé, ìgbésẹ̀ náà lówáyé láti mú àgbéga bá lílọ bíbọ̀ àwọn òsìsẹ́ alábo àmọ̀tẹ́kùn, OPC, àwọn ọdẹ tófimọ́ ikọ̀ vigilantee, láti mú àmú gbòrò dé bá isẹ́ wọn.

Nígbà tón fèsì, ọ̀gágba ilésẹ́ ọlọ́pa Èrúwà, ọ̀gbẹ́ni Peter Ugochucwu fi ẹ̀mí ìmore hàn sí olùdarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin, fún àtìlẹ́yìn tó se fún ẹ̀sọ́ alábo gbogbo.

Nígbà tón rọ àwọn èyàn láti túnbọ̀ sátìlẹyìn fún ilésẹ́ ọlọ́pa náà lọ́wọ́, sọwọ́ sí wọn, ọ̀gbẹ́ni Ugochuckwu wá fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé, ètò àbò yo tunbọ gbèrú si láwọn agbègbè náà.

Bákanà, alága, ìgbìmọ̀ àwọn olórí lágbègbè náà olooye Joseph Peluọla fi ìdùnú hàn lórí ìgbésẹ̀ olùdarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin nípa dídahun si ìbere àwọn èyàn lójú ọjọ́.

Láfẹ̀mọ̀júmọ́ ọjọ́ àikú Sunday tó kọjá, ni ìkọlù kan wáyé ní Ìgàngàn, lágbègbè ìjọba ìbílẹ̀ àríwá Ìbàràpá nínú èyí tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ti sọnù tọ́kẹ àimọye dukia sì jóná tófimọ́ àfin Ashigangan tìlú Ìgàngàn.

Folakemi Wojuade

News Yoruba

Adari ile igbimo Asofin Ipinle Oyo, Ogbeni Adebo Ogundoyin ti se ipade eto aabo pelu awon agbagba atawon olori iko alaabo to fi mo gbogbo awon toro kan nile ibarapa.

Ipade yi ko seyin akolu to waye lojo abameta nilu Igangan, nipa bi awon agbebon se kolu agbegbe naa leyi to ran awon eeyan ti ko din ni ogun sorun apapandodo pelu biba opo dukia je, Ogbeni Ogundoyin salaye wipe, ipade naa to waye nilu Ayete, nijoba Ibile Ariwa Ibarapa lo de le agbeyewo bi inkan se lo pelu iwadi lori ohun to se okunfa akolu naa, nidi ati le je kawon agbofinro duro deede lati koju akolu miinn to ba le fee waye.

Adari ile asofin naa wa rawo ebe sawon agbofinro pe ki won tu gbogbo igbo nla to wa lagbegbe naa yebe-yebe, ki won si se awari ibi ti awon odaran ba n fi ara sinko si lagbegbe naa, ki won le fi kele ofin gbe awon amookun sika eda naa.

Oga agba ilese Olopa agbegbe Ibarapa, Ogbeni Ojo Emmanuel wa so asodaju pe won ti ko awon iko Olopa de ilu Igangan ati agbegbe re fun ipese aabo to peye, bee lo kesi awon olugbe agbegbe naa pe ki won maa se atileyin fawon agboofinro fun ipese aabo to peye.

Okareh/Babatunde