Yoruba

Àwọn ọmọdé nílu ìbàdàn tíi solúùlu ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti késíjọba láti sàgbékalẹ̀ àwọn ìlànà kan tí yóò dábobo ọjọ́ ọ̀la wọn.

Lákokò tíwọ́n ńbá ilé-isẹ́ Radio Nigeria sọ̀rọ̀ ni wọ́n pè féyíì, pẹ̀lú àlàyé pé, àwọn ọjọ́ ọ̀la ilẹ̀ Nìajírìa, torina ló fi sepàtàkì fún ìjọba àtàwọn tọ́rọkàn, láti jẹ́ olótotọ́ nídi ìgbésẹ̀ dídàbòbò ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé.

Diẹ lára àwọn ògo wẹrẹ ọ̀hún kò sài tún rọ ìjọba láti pèsè ètò àbò tó gbópọn yíká àwọn ilé-ìwé gbogbo tó ńbẹ nílẹ̀ yíì.

Àwọn ọmọdé ọ̀hún wá fẹ̀mí ìmóòre wọn hàn sọ́lọrun ọba lórí bóse dá ẹ̀mí wọn sí, láti tún fojú gánní àyéjọ́ ọjọ àwọn ọmọdé fún tọdún yíì.

Int/Ololade Afọnja.

Yoruba

Alákoso fọ́rọ̀ àwọn obìnrin, arábìnrin Dame Tallen ti késí ìjọba àtàwọn tọ́rọ̀kàn láti wojùtú sí ìdúnkokò mọ́ ìgbáyégbádùn àwọn ọmọdé nílẹ̀ Nàijírìa èyí tí ìbẹ́sílẹ̀ àrùn Covid19 ńfà.

Alákoso sọ̀rọ̀ yí , nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti se ayẹyẹ àyájọ́ àwọn ọmọdé lágbeyé tó kò lóni.

Arábìnrin Tallen ńfẹ́ kí sísàmúlò àti dídàbòbò ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé múná dóko si.

Ó sàlàyé pé, ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé nínú abala òfin ọdún 2003, lóyẹ kí ìjọba àpapọ̀ àti ìpínlẹ̀ sàmúlò rẹ̀ lọ́nà tó yẹ.

Alákoso wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀, sáwọn tón gùnlé jíjí ọmọdé gbé fún gbigba owó ìtanràn, ni kí wọ́n fòpin sí irúfẹ́ ìwà ìbàjẹ́ yi ní kíakía.

Net/Ololade Afọnja