Yoruba

Òjísẹ́ Ọlọ́run pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìjọba tuntun

Àgbàgbà Bishop tìjọ Anglican lẹ́kùn Èkó, ẹni-ọ̀wọ̀ Humphrey Ọlumakaiye ti rọ gbogbo ọmọ ilẹ̀ yí láti gba ìyànsípò padà Àrẹ Muhammadu Buhari gẹ́gẹ́bí isẹ́ Ọlọ́run.

Ẹni-ọ̀wọ̀ Olumakaiye ló sọ̀rọ̀ yi nípinlẹ̀ Èkó, lásìkò tón bá akọròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria sọ̀rọ̀.

Ó sọ wípé Ọlọ́run gan ló yan Àrẹẹ Buhari fún orílẹ̀èdè Nàijírìa, ó wá rọ oníkòjikò láti sisẹ́ papọ̀ pẹ̀lú surù kílẹ̀ yi lé ni ìlọsíwájú tó yẹ.

Ẹni-ọ̀wọ̀ náà tún késí àwọn èyàn ilẹ̀ yí láifi ẹ̀sìn kówá se, láti wàní ìsọ̀kan àtàláfìa fún àgbéga ilẹ̀ Nàijírìa.

Ogunkọla/Kẹhinde

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *