Alákoso fún ilésẹ́ ọlapa nípinlẹ̀ Ọyọ, ọ̀gbẹ́ni Shina Olukọlu ti sèlérí fáwọn èyàn Òkè-Ògùn pé ètò àbò tó múnádóko yó wà fún ẹ̀mí àti dúkia àwọn èyàn agbègbè náà.

Ọgbẹni Olukolu ló sèlérí yi nílu Saki, lásìkò tó sàbẹ̀wò ẹnusẹ́ ságbègbè náà, tó sì késí àwọn olùgbé láti jẹ́ kámugbòrò bá ìbásepọ̀ lálafìa.

Bẹ́ẹ̀ lótún gba àwọn òsìsẹ́ ilésẹ́ ọlọ́pa níyànjú láti sisẹ́ wọn lọ́nà tótọ́ àti èyí tóyẹ, káwọn èyàn àwùjọ lèní ìgbẹkẹ̀lé nínú wọn.

Lásìkò àbẹ̀wò náà, alákoso fún ilésẹ́ ọlọ́pa tó ti fẹ̀yìntì, tó jẹ́ ọmọbíbí ìlú Saki, Àlhájì Suleman Oroyinyin rọ àwọn èyàn Òkè-Ògùn láti sàtìlẹ́yìn fún ilésẹ́ ọlọ́pa, kísẹ́ ọlọ́pa agbègbèlè rọrùn si.

Lára àwọn tó péjú pésẹ̀ síbi ìpàdé náà latirí, àwọn Ọba aládé, olóyè, òsìsẹ́ àjọ àbò, ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ láti Ìsẹ́yìn, àwọn àgbẹ̀ tófimọ́ àwọn tón da ẹran máàlu yíká agbègbè Òkè-Ògùn.

KemiOgunkọla/RasheedahMakinde

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *