Yoruba

Ìpínlẹ̀ Ọyọ gbé ìgbésẹ̀ lórí ilégbe ìrọ̀rùn

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ ti kéde ìpinu rẹ̀ láti ta àwọn ilégbe méjìdínlógójì tówà ní “Calton-Gate Estate” Àkóbọ̀ ìbàdàn fáwọn  arálu lówó tí o gajura lọ.

Alákoso fọ́rọ̀ ilẹ̀ ilégbe àti ìdàgbàsókè ẹsẹ̀kùkú, ọ̀gbẹ́ni Abiọdun Abdu-Raheem ló jẹ́ kọ́rọ̀ yi di mímọ̀ lásìkò tón se àbẹ̀wò sáwọn ilégbe tó jẹ́ tìjọba nílu’bàdàn.

Ọgbẹni Abdulraheem sọ pé, ìgbésẹ̀ náà wáyé, láti mú ìlérí èyí tí ìjọba tó wà lóde báyi se, lásìkò ìpolongo ìbò, lórí ìpèsè ilégbe tóworẹ̀ kò pọ̀ fáwọn èyàn  ìpínlẹ̀ Ọyọ.

Ó takasi pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èyàn nípinlẹ̀ Ọyọ ni wọ́n nílò, ilégbe èyí tó sì ti sí sílẹ̀ ni Calton Gate estate, tó sìní kíwọ́n gbé ìgbésẹ̀ láti ra lásìkò.

Alákoso shún tún wá fi aìdunu rẹ̀ hàn lórí báwọn èyàn kan, se se ọgbà yí ilẹ̀ wọn ká lágbègbè náà tí wọ́n kò sì ti kọ.

Kemi Ogunkọla/Iyabo Adebisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *