Yoruba

Alákoso pè fún àjọsepọ̀ tó lóórin láàrin àwọn iléésẹ́

Alákoso kejì fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè Ambassador Zubairu Dada, ti pè fún ìbásepọ̀ tó gbúmọ̀ láarin gbogbo àwọn lájọ-lájọ àti ẹ̀ka tó wà lábẹ́ ìsàkóso ọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ òkèrè.

Ó sọ̀rọ̀ yí nílu Abuja, lásìkò tón gba àwọn ìgbìmọ̀ aláse ẹ̀ka àtò gbogbo nílẹ̀ adúláwọ̀ lálejò ní ófìsì rẹ̀.

Alákoso kejì fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Ambassador Dada tẹnumọ pàtàkì ìbásepọ̀ tó gúnmọ́ láti àwọn ilésẹ́ yi kí wọ́n lè ní àseyọrí.

Óní ilẹ̀ Nàijírìa gbọdọ̀ ri dájú pé, wọ́n rí ànfàní tópọ̀ nínú ìdókowo papa lárin àwọn orílẹ̀èdè tówà nílẹ̀ adúláwọ̀.

Ó sì se ìlérí láti ri dájú pé ilésk ọ̀hún gbé àwọn ètò kalẹ̀ pẹ̀lú àjọsepọ̀ tó múnádóko, kí wọ́n lè s’àseyọrí.

Kemi Ogunkọla/Sheriff Nasirudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *