Ìgbìmọ̀ tẹkótó ilé tó ńrísí idàgbàsókè ẹkùn Niger Dẹlta, NDDC, ti kanpá fún ọ̀gá àgbà bánki àpapọ̀ ilẹ̀ yíì Godwin Emefiele láti farahàn níwájú ilé.
Alága, ìgbìmọ̀ ọ̀hún, ọ̀gbẹ́ni Nicholas Ossai, sọ fáwọn oníròyìn nílu Abuja, wípé àwọn ti gba àkọsílẹ̀ láti ilésẹ́ bánki àpapọ̀ lórí àwọn isẹ́ àkànse lẹ́kùn Niger Delta tótijẹ́ pípatì .
Ó sàlàyé pé, ọ́gbẹ́ni Emefiele àti ìgbìmọ̀ tó ńrísí ìdàgbàsókè ẹkùn Niger Dẹlta gbọ́dọ̀ farahàn níwájú ìgbìmọ̀ ilé ọ̀hún.
Ìgbímọ̀ tẹkótó ilé tún sàtúnpe ọ̀gbẹ́ni Emefiele lẹ́yìn tó kọ̀ láti farahàn níwájú ilé lákokò tí wọ́n se ìwádi lọ́jọ́ ìsẹ́gun tókọjá.
Kẹmi Ogunkọla