News

Gómìnà Seyi Makinde sèlérí àgbéga pápákọ̀ òfurufú tìlú Ìbàdàn

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ, Seyi Makinde tún ti sọ nípa ìpinnu rẹ̀ láti mú àgbéga báà pápákọ̀ òfurufú tó wà nílu ìbádán kí wọ́n bà le ma fi ẹrù ńláńlá ránsẹ́ nípasẹ̀ pápákọ̀ ọ̀ún àti kí àwọn èèyàn lè ma wọ ọkọ̀ òfurufú ló sí ilẹ̀ òkèèrè láti ibẹ̀.

Gómìnà Makinde sọ pé, òun ti ń báà àjọ iléésẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó ń bójútó àwọn papakọ̀ òfurufú FAAN, sọ̀rọ̀ nípa àwọn èròngbà oun yi.

Abúlé Àjía tó wà níjọba ìbílẹ̀ Ọna Ara nípinlẹ̀ Ọyọ, ni Gómìnà Makinde ti sọ̀rọ̀ yí nígbàtí àwọn èèyàn abúlé nà, tó jẹ́ abúlé àwọn baba ńlá se ètò àyẹ́sí fun.

Ó ní òun yo ri dáa’jú pé ìdágbásókè tó jẹ́ àrígbámú káari gbogbo ìpínlẹ̀ Ọyọ, nítorí tàwọn aráalu tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú òun, tí wọ́n sì dìbò gbé òun sórí àlééfà.

Kẹmi Ogunkọla/Oluwayẹmisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *