Ìdúnadúrà tó ń wáyé láarin ìjọba àpapọ̀ àtẹgbẹ́ òsìsẹ́ lórí ọ̀rọ̀ owó osù àwọn òsìsẹ́ tókéré jùlọtún bẹ̀rẹ̀ lóni nílu Abuja.

Ìpàdé náà tí wọn ò forí rẹ̀ tìsíbìkan lána niwọ́n tún gùnlé ní dédé ago méjì ọ̀sán òní.

Igbákejì àarẹ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ nílẹ̀ yíì, ọ̀gbẹ́ni Amaechi Asugunim, fi ìrètí hàn pe, ìpàdé náà yóò so èso rere.

Nínú ọ̀rọ̀ tìẹ, alákoso fọ́rọ̀ isẹ́ àti ìgbanisísẹ́, ọ̀mọ̀wé Chris Ngige, sàlàyé pé, bíjọba àpapọ̀ bá se ohun táwọn òsìsẹ́ ńbèrè fún, yóò mú kétò ọ̀rọ̀ ajé ilẹ̀ yíì pakasọ.

Bí ìjọba àpapọ̀ bá tẹ́wọ́gba ohun tẹ́gbẹ́ òsìsẹ́ ń bèrè fún, ó tímọ̀dì pé, bí àbá ètò ìsúná ọdún 2020, láwọn òsìsẹ́ ọba bi milliọnu kan àbọ̀ yóò máà gbà.

A ó rántí pé ọ̀sẹ̀ tókọjá lẹgbẹ́ òsìsẹ́ sèlérí pé, àwọn yóò gùnlé ìyansẹ́lódì yíká orílẹ̀èdè bíjọba àpapọ̀ bá kùnà láti sàmúlò owó osù tuntu.

Kẹmi Ogunkọla/Ọmọlọla Alamu

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *