Àarẹ ilé ìgbìmọ̀ asòfin, Sẹ́nátọ̀ Ahmed Lawan ti kéde pé, gbogbo àwọn ilé-isẹ́ àti lájọlájọ,  gbọ́dọ̀ wa farahàn níwájú ilé láti wá sọ̀rọ̀ gbe àbá ètò ìsúná wọn lẹ́yìn, títí ọjọ́ kọkọ̀ndínlọ́gbọ̀n osù yíì.

Asòfin Lawan sọpé, ìgbésẹ̀ yíì ló wáyé níbamu pẹ̀lú bí wọ́n se ka àbá ètò ìsúná ọdún 2020 fún igbákejì nílé asòfin àgbà, tíwọ́n sì ti késí ìgbìmọ̀ tẹkótóilé lórí àatò gbogbo láti sisẹ́ lórí rẹ̀ kíwọ́n sì wá fi àbọ̀ jẹ́ ilé láarin ọ̀sẹ̀ méjì.

Sẹ́nétọ̀ Lawọn kò sài tun tọ́kasi pé, ilé isẹ́ ẹ̀ka tàbí àjọ ìjọba yóòwu tó bá kùnà láti wá farahàn níwájú ilé kó tó di gbèdéke àkókò tíwọ́n làkalẹ̀ fún wọn, kò gbàgbé lórí ìgbésẹ̀ sísọ̀rọ̀ gbe àbá ètò ìsúná rẹ̀ lẹ́yìn.

Kẹmi Ogunkọla/Modupe Tọba

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *