Ìjọba àpapọ̀ ti sọ pé, kòní pẹ́ tó n yóò fi sàgbéyẹ̀wò owó osù gbogbo àwọn tó dipò òsèlú mú pátá.

Ìlú Abuja lalákoso fọ́rọ̀ isẹ́ àti ìgbanisísẹ́, ọ̀mọ̀wé Chris Ngige ti sísọ lójú ọ̀rọ̀ yíì, lákokò àbẹ̀wò ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ láwọn ìjọba ìbílẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bó se wípé, ó sepàtàkì kíwọ́n sàgbéyẹ̀wò owó osù àtàwọn àjẹmọ́nú tíwọ́n ńfáwọn tó dipò òsèlú mú, tófimọ́ táwọn òsìsẹ́ kan láwọn ilé-isẹ́ àtàwọn àjọ ìjọba.

Ọmọwe Ngige kò sài tún sọ́ọ́di mímọ̀ pe, ìgbìmọ̀ náà yóò tun bojúwo ìlànà ìsanwó àwọn òsìsẹ́ ìjọba, lẹ́yìn àyẹ̀wò fínífíní tíwọ́n bá ti se lórí rẹ̀.

Kẹmi Ogunkọla/Seyifunmi Ọlarinde

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *