Yoruba

Àjọ NÓÀ pè fún àmúlò òfin tó wà fún òmìnira lílo àkọsílẹ̀ ìjọba

Àwọn tọrọ kàn ti pè fún àmúlò òfin tó wà fún sìsámúlo àwọn àkọsílẹ̀ láìsí ifoya.

Ọ̀rọ̀ yi ló jé jáde níbi ìpàdé apero tí àjọ tó wà fún itaniji ará ìlú sí ojúṣe wọn NOA gbé kalẹ nilu Ilorin ńipinle Kwara.

Oga agba àjọ NOA, ńipinle Kwara, Ogbeni Olusegun Adeyemi ṣàpèjúwe sìsámúlo òfin yí bí ohun tó jé alabala méjì nítorípé bí àwọn ará ìlú kò bá bèrè ọ̀rọ̀, ìjọba tàbí àwọn lajolajo kò ní lee dáhùn.

Ogbéni Adeyemi ní àjọ NOA fún nkan bíi ọdún mẹsan sẹ́yìn tí ńlewaju nìdi rírọ àwọn ènìyàn láti máa samulo àwọn àkọsílẹ̀ àti rírọ àwọn ilé isẹ ìjọba àti lajolajo láti máa pèsè àwọn àkọsílẹ̀ yí fún lílo.

Alábòójútó foro ìròyìn ńipinle náà, Alhaji Murtala Olanrewaju ẹnití ìgbàkejì oga lèka ilaniloye ará ìlú Arábìnrin Christiana Ashonibare ṣojú fún ní sìsámúlo òfin yí ní anfaani tó pọ̀ lára rẹ ni ibasepo tó gunmo láàrín ìjọba àti àwọn ará ìlú.

Yẹmisi Dada/Kẹmi Ogunkọla 

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *