Yoruba

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ogun ti ilé isẹ méjìlá pa fún biba àyíká jẹ

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ogun ti gbé àwọn ilé isẹ méjìlá kan tipa lágbègbè Ogijo ńipinle náà, nítorí titipa sofin atìlànà toromo biba àyíká jẹ.

Alákoso foro àyíká ńipinle náà, ogbeni Abiodun Abudu-Balogun tó lé waju ìkórè nidi ètò itopinpin náà, ṣàlàyé pé, àwọn gbé àwọn ilé isẹ náà tipa nítorí báwọn nkan ti pèsè bayika dọ́gba, pẹ̀lú àfikún pé, ìjọba kọ́ni sí àwọn ilé isẹ náà, afìgbà tiwọn bá s’afihàn ọ̀nà tiwọn fegbegba láti fòpin sí biba àyíká.

Alákoso náà tẹnumo pé, ìjọba tó wà lóde báyìí ti ṣetán láti gbé ilé isẹ yòówù tó bá ń kó ìnira báwọn èèyàn agbègbè ibi tó wà tipa laifi bose tóbi tó tàbí igbanisise, Ogbeni Abudu-Balogun wá gbawon ilé isẹ yòókù tó wà nìpínlè Ogun táwọn ko ti fowokan níyànjú láti sọ abo àyíká dore wọn, kí wọ́n tótó rẹ sije akọmona, nítorí pé ìjọba kọ́ni faaye gba àyíká bibaje àtàwọn ìwà kòtò min-ín sayika.

Dada Yemisi/Ogunkola Kemi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *