Gẹ́gẹ́bí ara ìgbésẹ̀ tíjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀, láti pinwọ́ ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná, àtàwọn ìjàmbá miràn lórílẹ̀èdè yí, ilésẹ́ panápaná nílẹ̀ yí ti ra àwọn on èlò sí ẹ̀ka ọ́fìsì rẹ̀ nípinlẹ̀ ọyọ pllú àfikún àwọn ọkọ̀ ńláńlá méjì tín pa iná.

Olùdarí àgbà fún ilésẹ́ náà, Alhaji Liman Ibrahim ló sọ̀rọ̀ yí, lásìkò tó lọ se ẹkúsẹ́ ńbẹunsí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde

Olùdarí àgbà ọ̀hún, tí ọ̀gá lẹ́kùn yí sojúfún ọ̀gbẹ́ni Kẹhinde Ajasa, sọ pé ọkọ̀ ńlá méjèjì tó jẹ́ ti ayé òde òní, ni wọ́n ma gbé fún ilésẹ́ èyí tó wà níbàdàn lọ́sẹ̀ tónbọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ ọyọ, onímọ̀ ẹ̀rọ Makinde, tí igbákejì Gómìnà onímọ̀ ẹ̀rọ Rauf Ọlaniyan sojúfún tọ̀kasi pé àwọn ọkọ̀ yi yo sèrànwọ́ fún ìpínlẹ̀  ọ̀yọ́ lọ́jọ́ iwájú láti gba agbára lọ́wọ́ ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná.

Onímọ̀ ẹ̀rọ Ọlaniyan wá fi ẹ̀mí ìmore hàn sí ìjọba àpapọ̀ fún àwọn on èlò tí wọ́n gbé fún ilésẹ́ panápaná.

Oluwayẹmisi Dada

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *