Yoruba

Orílẹ̀ èdè Nàijírìa ti kúrò láwùjọ àwọn tí wọ́n ní àrùn rọmọlápá rọmọ lẹ́sẹ̀ – W.H.O

Àjọ elétò ìlera lágbyé W.H.O ti kéde pé, ilẹ̀ Nàijírìa rọmọlápárọmọlẹ́sẹ́ ti jàjàbọ́ kúrò lọ́wọ́ àrù polio.

Àjọ náà lórí òpó ẹ̀rọ abẹ́yẹfò rẹ̀, iyin twitter sọ pé ní lọ́lọ́ yí orílẹ̀ èdè méjì péré ni àrùn polio bá ńfira, èyí ló sì ti mú kó jẹ́ pé gbogbo àgbáyé ló ti fẹ́ fòpin s;i àrùn náà pátápátá.

Olùdarí àgbà fún W.H.O, Dókítà Margret Chan, sọ pé ìgbésẹ̀ àti ìfọkàntán èyí tí orílẹ̀èdè Nàijírìa lò láti móríbọ̀ kúrò nínú àrùn náà ló yẹ kó tesíwàjú kí gbogbo ilẹ̀ adúláwọ̀ náà lè mógojà.

Ilẹ̀ Nàijírìa lóti wá lára àwọn orílẹ̀èdè tí wọ́n ti jàjàbọ́ kúrò lọ́wọ́ àrùn polio pẹ̀lú àwọn àkọlé èyí tí wọ́n tíì tò sí tije ìtẹ́wọ́gbà lájọ agbègbè ilẹ̀ adúláwọ̀ tón sisẹ́ láti fòpin sí àrùn polio.

Dada Oluwayẹmisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *