Yoruba

Àlúfà rọ àwọn ọmọlẹ̀yìn Krístì láti gbé ìgbé-ayé íbẹ̀rù Ọlọ́run

Gbígbé ìgbé ayé tó ní ìtumọ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni ó yẹkí ó lékè ọkàn gbogbo ènìyàn tó bá wà láyé.

Venerable Dan Oyewọle tilé ìjọsìn St Mark Anglican Church, Olómi nílu ìbàdàn ló sọ̀rọ̀ yí nínú ìwásù rẹ̀ níbi ìsìnkú alága tẹ́lẹ̀rí fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Shooting Stars tìlú ìbàdàn, alàgbà Bọde Oyewọle.

Venerable Oyewọle ní olóògbe tise ìwọ̀n tó lè se nínú ayé, tó wá rọ àwọn ọmọlẹ́yìn Krítì láti gbé ìgbé ayé oníwà bí Ọlọ́run títí dópin.

Ó fikun wípé, ó yẹkí gbogbo ènìyàn máà rántí pé gbèsè ni ikú jẹ́ fún gbogbo ènìyàn.

Akọ̀ròyìn tó bá wọn péjú síbi ètò ìsìnkú náà ni àwọn tó wá síbi ètò ọ̀ún ni wọ́n tẹ̀lé ìlànà ìdáàbòbò lòdì sí àrùn covid-19 lẹ́nu ọ̀nà tí wọ́n sì lo ìbomú láiyọ títakété síraẹni sílẹ̀.

Alàgbà Oyewọle ló jàde láyé lọ́jọ́ ìsẹ́gun, ọjọ́ kẹrìnlá osù yí lẹ́ni ọdún méjìdín láàdọrun.

Taiwo Akinọla/Yẹmisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *