Yoruba

Àarẹ Buhari pàsẹ ìwádi kíàkíà lórí ọ̀rọ̀ àjọ NDDC

Àarẹ Muhammadu Buhari ti fèsì lórí ìwádi owó tó tó ogójì billiọnu naira tí àjọ tó wà fún ìdàgbàsókè agbègbè Niger Delta NDDC, èyítí ó ti ńfa awuyewuye láàrin ilé ìgbìmọ̀ asòfin àpapọ̀ àti àwọn adelé alásẹ àjọ náà.

Àarẹ Buhari ti wá pàsẹ kí isẹ́ ìwádi tó yá ní kọ́nmọ́kánmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ lórí isẹ́ àwọn ìgbìmọ̀ alásẹ àjọ náà.

Ó ní ó yẹkí ìgbésẹ̀ tó gúnmọ́ wà láàrin àwọn agbófinró, àwọn àjọ tó ńse ìwádi àti ilé ìgbìmọ̀ asòfin àpapọ̀ láti léè tètè mọ àwọn ìsòro tó ńdí ìsowó síse ìgbìmọ̀ náà lọ́wọ́ àti àwọn oun tí ó ńdí ìlọsíwájú agbègbè Niger Delta lọ́wọ́.

Àarẹ Buhari ẹnití ó jẹ́jẹ láti fìyà tó tọ́ jẹ ẹnikẹ́ni tí aje ìwà ìbàjẹ́ á sí mọ́ lórí, wá jẹ́jẹ ìpinu rẹ̀ làti túsu désàlẹ̀ ìkòkò lórí ọ̀rọ̀ tó ńjà rànyìrànyí ọ̀ún.

Yẹmisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *