Yoruba

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ, yo bẹ̀rẹ̀ siní pàdé lórí afẹ́fẹ́

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ yóò bẹ̀rẹ̀ sini gbé àwọn ìpàdé ilé sórí afẹ́fẹ́, láti jẹ́kí àwọn aráàlu mọ bóseńlọ.

Adarí ilé, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin sọ èyí di mímọ̀ nígbà tó sàgbé kalẹ̀ ìwé ìròyìn ilẹ̀ àkókò èyí tíwọ́n pèní ‘Ọyọ Specter’’.

Ọgbẹni Ogundoyin sopé gbogbo ètò tító fún gbígbé àwọn ìpàdé ilé-sórí afẹ́fẹ́ bóbá se ńwáyé pẹ̀lú àlàyé pé ìgbésẹ̀ náà wáyé láti mú ǹkan yàtọ̀ nílé asòfin kẹsan.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, alága àjọ ọ̀hún, ọ̀mọ̀wé Abudulwasi Musah, gbóríyìn fún àwọn adarí ilé asòfin kẹsan fún isẹ́ takun-takun láti sàseyọ́rí nídi àfojúsùn wọn.

Lára àwọn ǹkan tíwọ̀n sọ níbi ayẹyẹ náà níì ìgbáyégbádùn àwọn òsìsẹ́ ilé asòfin àti tàjọ náà pẹ̀lú tófimọ́ àtúnse àwọn òfin tóníse pẹ̀lú ilé

Afonja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *