Yoruba

Tolulọpẹ Arotile: Obìnrin Àkọ́kọ́ tó wa báàlu ọkọ̀ ìja ni wọ́n ti sin sílé ìsìnkú ọmọ ológun

Wọ́n ti sin òkú arábìnrin àkọ́kọ́ tó wa báàlu ìjagun, Tolulọpẹ Arotile tó papòdà lọ́jọ́ kẹrìnlá osù keje ọdún yi.

Ayẹyẹ ìsìnkú lówáyé ní ilé ìsìnkú àwọn olóògun tó wà lágbègbè pápákọ̀ òfurufún Nnamdi Azikiwe Abuja, lábẹ́ àbò tó gbópọn, ìwọ̀nba àlejò àti mọ̀lẹ́bí nìkan ni wọ́n gbà láye wọ ilé ìsìnkú náà.

Ìròyìn sọpé olùdarí ọmọ ogun ojú òfurufú, Abubakar Sadique, Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi Yahaya Bello, alága ìgbìmọ̀ tẹkótó lórí ọ̀rọ̀ ológun òfurufú Balla Nalla ni wọn wà níbi ètò náà.

Nígbà tóń ka ìwé àwọn on ìtọ́kasí ológbe ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí wọ́n tún jọ kàwé pọ̀, ọ̀gágun J.chukwu tọ́kasi pé lára àwọn on àmúyẹ tí Tolulọpẹ Arotile ti ní bí wọ́n se fihan Àrẹ Muhammadu Buhari nínú osù kejì ọdún yi, tí wọ́n sì sísọ lójú rẹ̀ gẹ́gẹ́bí obìnrin àkọ́kọ́ tí yo wa báàlù ológun.

Ọjọ́ kẹtàlá osù kejìláọdún 1995 ni wọn bí Tolulọpẹ Sarah Arotile nílé mọ̀lẹ́bí ọ̀gbẹ́ni àti Arábìnrin Akintunde Arotile nípinlẹ̀ Kogi, tósì jáde láyé lọ́jọ́ kẹrìnlá osù keje ọdún 2020.

Afọnja    

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *