Yoruba

Ijoba apapo ati ojo WAEC fenuko lori akoko idanwo oniwe mewa

Ijoba apapo ti jo s’adehun pelu ajo to nse kokari idanwo oniwe mewa, WAEC, lori akoko idanwo.

Alakoso keji foro Eko nile yi, Ogbeni Emeka Nwajuiba lo soro yi nibi ijabo igbimo amuseya ijoba apapo lori arun Covid-19.

Gegebi o se so, o ni adehun ti won se je lori idanwo to nbo lona lori awon ise ti won maa nse nile yi.

O fikun wipe won mo gbogbo nkan tin lo nipaapajulo l’ori iwole pada awon ile iwe, alakoso keji ohun wa kilo wipe aabo lo yeki won jeki o leke ninu gbogbo ohun ti won ban se.

Ogbeni Nwajuba ni pelu bi won ti se pe ipade pelu awon toro eko kan lojo kokandinlogbon osu yi, ipade miran yio waye logbon ojo lati bojuwo bi nkan ti se nlo leka eto eko. 

Yemisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *