Yoruba

Gomina Sanwo-Olu beere fun sunru bi won ti se ti afara 3rd Mainland

Gomina Ipinle Eko, Babajide Sanwo-Olu ti ro awon olugbe ilu Eko lati se suuru lori isoro ti won yio foju wina re laarin osu mega ti won fe fi ti abala kan afara 3rd Mainland bere lati oni lo.

O  soro yi lasiko ti o ngbalejo oga ajo eso oju popo FRSC tuntun nipinle Eko, Ogbeni Olusegun Ogungbemide ni ile ijoba to was ni Marina.

Gomina Sanwo-Olu wa seleri fun awon omo ile yi wipe isoro die ni won yio koju nitoriwipe awon osise ajo to nrisi igbokegbodo oko nipinle Eko LATSMA ni won yio ko lo sawon oju popo lati maa dari oko.

O ni titi afara yi ti opo oko maa nrin ni ko see ye sile nitoripe o ti ngbo layiti ayewo ti ijoba apapo se fihan.

Gomina Sanwo-Olu ni ijoba ti satunse awon ona miran ti awon eniyan lee rin lari lee muki lilo bibo oko tubo rorun.

Nigbati o nfesi, Ogbeni Ogungbemide ni ajo FRCN yio fowosowopo pelu ajo LATSMA lati bojuto lilo bibo oko nipinle naa.

Yemisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *