Yoruba

Ilé isẹ́ Àarẹ pàrọwà fẹ́gbẹ́ TUC lórí ìfẹ̀hùnúhàn tí wọ́n fẹ́ se

Ilé isẹ́ àarẹ ti késí ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ T.U.C láti sẹ́wẹ́lé ìfẹ̀hònú hàn káàkiri ilẹ̀ yí tí wọ́n fẹ́ gùnlé lórí bí àarẹ Muhammadu Buhari ti se káwọ́ gbera lórí oníruru ìwà àjẹbánu tí wọ́n tú síta láipẹ yí.

Àrọwà yi ni ó wà nínú àtẹ̀jáde láti ọwọ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì sí àarẹ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn àti ìponlogo Mallam Garba Sheu.

Ó ní kò sí ìdí kankan fún ìfẹ̀hònúhàn náà nítorípé àwọn ìwà àjẹbánu tí wọ́n ńwàdí nínú àjọ tó ńrísí ìdàgbàsókè agbègbè Niger Delta, NDDC, tí àjọ tó ńrísí àpò àsùwọ̀n adójútófo, NSITF àti tínú àjọ tó ńgbógunti ìwà àjẹbánu àti àwọn ìwà ọ̀daràn EFCC, ni isẹ́ sí ńlọ lórí rẹ̀ láti ọwọ́ ẹ̀ka alásẹ àti asòfin.

Àtẹ̀jáde náà wá késí ẹgbẹ́ TUC, láti se súùrù kí wọ́n fi parí ìwádi tó ńlọ lọ̀wọ̀

Yẹmisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *