Yoruba

Ijoba Pase Fun Ileese Olopa Pe Ki Won Se Awari Afurasi Apaniyan To Salo Lakata Won

Ijoba ipinle Oyo ti soo di mimo pe gbogbo igbese to ye lo ti nje gbigbe nidi ati rii daju pe eni ti fi kele ofin gbe afunrasi to wa nidi isele isekupani lagbegbe Akinyele, iyen Sunday Shodipe, eni to salo mo awon Olopa lowo.

Won tun seleri ati mu alaafia ohun ifokanbale joba lagbegbe Akinyele.

Gomina ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde lo seleri yi lasiko ipade eto aabo to waye pelu awon  toro kan Nijoba Ibile Akinyele

Gomina Seyi Makinde, eni ti oludamoran Pataki re foro aabo, Ogbeni Fatai Owoseni soju fun gba awon osise alaabo nimoran pe ki won se ise pelu awon araalu lati fi le mu awon odaran to n yo won lenu lagbegbe naa.

Ogbeni Owoseni wa salaye igbonkanle re pea won toro eto aabo gberu nijoba ibile Akinyee ti fohun sokan lori ajosepo pelu ileese Olopa, lati wagbo dekun fawon apanijaye eda to wa lagbegbe naa.

Ninu oro re Alaga fidihe nijoba ibile Akinyele, to wa ni Moniya, Ogbeni Taoheed Adedigba dupe lowo Gomina seyi Makinde fun bo se mu eto aabo ro toto lagbegbe naa.

Babatunde Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *