Yoruba

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Èkìtì, buwọlu orúkọ àwọn méje tójẹ́ fífí sọwọ́ gẹ́ẹ̀gẹ́ bí alákoso

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Èkìtì tí bowọlu àwọn alákoso méje tí Gómìnà Kayọde Fayẹmi fi sọwọ́ sílé láipẹ yíì.

Lásìkò ètò náà, diẹ lára àwọn asòfin lára èyí tarirí igbákejì adarí ilé, ọ̀gbẹ́ni Akeem Jamiu àti ọ̀gbẹ́ni Aribasoye láti ẹkùn ìdìbò Ìkọ̀lé kiní, bere ọ̀kan-òjọ̀kan ìbere lọ́wọ́ àwọn alákoso tíwọ́n forúkọ wọn sọwọ́ ọ̀hún lórí isẹ́ tíwọ́n yàn láàyo.

Ẹwẹ, ilé buwọlu ìyànsípò àwọn alákoso náà, tí wọ́n sọ̀rọ̀ wọn láti sisẹ́ wọn bíì sẹ, kíwọn sì ma jáà àwọn tónígbàgbọ́ nínú wọn, ní tọmọ̀n.

Lára àwọn tí wọ́n yàn sípò níì, Àlhájà Maryam Ogunlade, láti Èmùré, alága tẹ́lẹ̀ fẹ́gbẹ́ òsèlù Labour, ọ̀gbẹ́ni Akin Ọmọlee láti Ọyẹ́, alákoso tẹ́lẹ̀rí, ọ̀túnba Diran Adesua.

Àwọn tóòku níì olóyè Ọlabọde Adetoyi, Mọba, ọ̀mọ̀wé Ọlabimpe Adarye, ọ̀mọ̀wé Oye Filani Ìkọ̀lé tófimọ́ ọmọbaa Iyabọ Fakunle.

Nínú ọ̀rọ̀, àwọn tíwọ́n yàn sípò ọ̀hún wọ́n fọwọ́ ìgbáradì wọn sọ̀yà, láti mú àgbéga bá ètò àti òlànà ìsèjọba ti Gómìnà Fayẹmi léwéjú.

Amos Ogunrinde/Elizabeth Idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *