Yoruba

Alekun owo epo betirolu yio sakoba feto oro aje – awon onisowo

Awon olugbe ilu oyo, paapa julo awon alajapa niwon ti sapejuwe bowo epo se tun sadede gbenu soke bayii gegebi egbinrin ote, to je pe base npa kan lomin tun n ru.

Akoba to ohun, ti beresi ni se feto oro aje ati irin ajo bayii lawon onisowo npejo so kaakiri ninu oko ati lawon oja.

 Awon onisowo naa, atawon awako salaye pe, koye kijobafi aaye gba ohunkohun to ba le fikun inira tara ilu nla koja lowolowo, nitori owe Yoruba toso pe, oosa bo le gbe mi, semi boo se bami.

 Nigba tawon naa n benuatelu ona eburu towo epo gba gbenu soke, ero oko meji, ogbeni Afeez Rafiu ati Dele Abokede ro ijoba lati tete satunse si.

 Nibayina, owo oko ti gbenu soke lawon opopona to wa silu ibadan lati Ogbomoso, Oyo, Iseyin, eyito mu kawon alajapa to segbe titi lawon ilu wonyii.

Folakemi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *