Yoruba

Awon awako ti fero Okan won han lori alekun owo ori epo betirolu

Awon awako ero atawon aladani nilu Ibadan ti koro oju si alekun to de ba owo ori epo lati aadojo naira o din naira meji si ogojo naira, fun jala epo kan.

 Akoroyin ile ise Radio Nigeria to topinpin boro naa seri laarin igbooro ilu Ibadan jabo pe, opo awon ile epo lo n ta eroja naa laarin Aadojo naira o din naira kan si ogojo naira, nigba tawon Alagbata kan n ta tiwon ni iye titele pelu alaye pe, awon n duro de ase latolulese won.

 Die lara awon olugbe to ba, oniroyin ile ise wa soro sope, ko seni talekun to de ba owo ori epo naa, koni se akoba fun.

 Meji Lara awon awako ero , Ogbeni Tunde Makinde ati Ogbeni Oyedele salawu dijo sope, owon gogo epo betirolu maa  sakoba ti ko legbe feto oro aje won.

 Ana ode yii, niwon kede alekun to deba jala epo betirolu kan latodo Ajo ton risi idiyele ori epo lati Aadojo naira o din naira meji si ogojo naira.

Folakemi Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *