Yoruba

Ijọba ìpínlẹ̀ Ògùn sèlérí láti sàmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ, kagbega lè débá ìlànà ètò ẹ̀kọ́

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn ti sọ pàtàkì lílo ìmọ̀ ẹ̀rọ láti fi kọ́ni láti mú kí àgbéga dé bá ẹ̀ka ètò níbamu pẹ̀lú bí wọ́n tínse láwọn orílẹ̀ èdè tó ti gòkè àgbà.

Olùdámọ́ran sí Gómìnà ìpínll Ògùn lórí ètò ẹ̀kọ iléwe alákọbẹ̀rẹ̀ àti girama Arábìnrin Ronkẹ Soyọmbọ, ló sọ̀rọ̀ yí níbi àpérò kan tó wáyé, láti sáàmì àjọyọ̀ mimọko moka, fún tọdún 2020, èyí tí wọ́n pè àkòrí rẹ̀ ní kókọ́ni nípa sísàmúlò ìmọ̀ ẹ̀rọ science lásìkò ìpèníjà ìtànkálẹ̀ àrùn covid-19 papa, isẹ́ tó wà níwájú olukọ àti ìpèníjà tó sẹ̀sẹ̀ kó súyọ.

Arábìnrin Soyọmbọ tọ́kasi pé, óti pa dandan láti róò àwọn olùkọ́ lágbára níbamu pẹ̀lú on gbogbo tí wọ́n yo nílò fún kíkọ́ akẹkọ lásìkò ìtànkálẹ̀ àrùn covid-19.

Nínú ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀tọ̀ àwọn onímọ̀ nípa ètò ẹ̀kọ́, ọ̀jọ̀gbọ́n Adejọkẹ Jibowo láti ilé ẹ̀kọ́ gíga versity Ọlabisi Ọnabanjọ àti ọ̀gbẹ́ni Joseph Adetọna láti àjọ tó n mójútó ìdánwò àsejáde nílé wé girama WAEC, pé àwọn tọ́rọ̀ ètò ẹ̀kọ́ kàn gbọ̀ngbọ̀n láti sàmúlò ìlànà ẹ̀kọ́ni àtìjọ àti tòde òní, kí àyípadà tó yẹ le wáyé léka ètò ẹ̀kọ́.  

Afonja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *