Yoruba

Ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìse ìlú’bàdàn lájọsepọ̀ pẹ̀lú agbègbè tó yíká lórí dídẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn covid 19

Gẹ́gẹ́bí ara akitiyan láti gbaradì fún sísí iléwe padà nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ ìgbìmọ̀ aláse ilé-ẹ̀kọ́ gbogbonìse ìbàdàn ti se ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn bàbá onílé tó wà lágbègbè ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún.

Ìpàdé náà ni ówáyé láti jíròrò lórí ọ̀nà tí wọ́n yo fi dẹ́kun ìtànkálẹ̀ àrùn covid 19, ètò àbò tó mẹ́hẹ àti wiwọ aisọ tí kò bójúmu lárin àwọn akẹ́kọ.

Nígbà tón sọ̀rọ̀, gíwá ilé ẹ̀kọ́ gbogbnìse ìbàdàn, ọ̀jọ̀gbọ́n Kazeem Adebiyi sàlàyé pé ilé-ẹ̀kọ́ náà tín gbé ìgbásẹ̀ láti wójùtú sétò àbò tó mẹ́hẹ àti wíwọ asọ tọmọluabi, sáàjú àsìkò táwọn akẹ́kọ yo wọlé padà.

Nínú ọ̀rọ̀ olùdarí kan lẹ́ka ìròyìn àti ọ̀rọ̀ tó lọ ilésẹ́ Radio Nigeria ẹkùn ìbàdàn Àlhájì Bashir Ọmọtọshọ àti àwọn tónílé lágbègbè náà, sèlérí láti ma se ìpàdé pọ̀ láwọn agbègbè náà láti wagbo dẹ́kun fáwọn ìwà ìbàjẹ́ tó sábà má ń súyọ lárin àwọn akẹ́kọ.

Lára àwọn asojú agbègbè tó wà níbi ìpàdé náà latirí asojú láti agbègbè Alaro, Apẹtẹ, Sango, Ararọmi Ijokodo àti Awọtan.

Famakin/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *