Àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ yí, INEC, ti ní ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná tó wáyé lápá ibìkan nílé isẹ́ nà tó wà nílu Àkúrẹ́ kò ní nípa lórí ètò ìdìbò Gómìnà tí yio wáyé ní ọjọ́ kẹwa osù tó ńbọ̀ nípinll Òndó.

Alága ẹ̀ka tó wà fún ìdánilẹ̀kọ olùdìbò nínú àjọ ọ̀ún, ọ̀gbẹ́ni Festus Okoye ló sọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ nígbàtí ó ńsọ̀rọ̀ lórí ìjàmbá iná náà.

Ọgbẹni Okoye wá ní kí àwọn ẹgbẹ́ òsèlú tó fẹ́ kópa nínú ètò ìdìbò náà máà se jk pé àjọ elétò ìdìbò yóò sán gbogbo ọ̀nà láti sàgbékalẹ̀ ẹ̀rọ tó ń sàyẹ̀wò káàdi olùdìbò mín-in, ni wọ́n bá gba tó jẹ́ pé, ètò ìdìbò ọ̀hún nìkan lówà fún ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Alákoso náà kò sài tọ́kasi pé, ó lé ẹgbẹ̀rún márun àwọn ẹ̀rọ ọ̀hún tó jóná sínú ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná tó wáyé, tó sì fikun pé, àjọ INEC, yóò sèwádíì fínífíní lórí ohun tó sokùnfà ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná náà.

Abudu/Wojuade  

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *