Yoruba

Alága àjọ SUBEB fi gbèdéke síta fún píparí isẹ́ àkànse àwọn ilé-ìwé girama

Alága ìgbìmọ̀ tón rísí ètò ẹ̀kọ́ káríayé nípinlẹ̀ Èkìtì, ọ̀jọ̀gbọ́n Fẹmi Kinwumi ti fi gbèdéke ìparí osù yíì lélẹ̀ fáwọn agbasẹ́ se tó wà nídi isẹ́ àkànse àwọn ilé-ìwé girama mẹ́rin tíjọba sẹ̀sẹ̀ dá sílẹ̀, láti fi parí isẹ́ àkànse ọ̀hún.

Ìlú Adó-Èkìtì ló ti kéde gbèdéke ọhun lákokò ìpàdé kan tó se pẹ̀lú àwọn agbasẹ́ se náà.

Ọjọgbọn Akinwumi tẹnumọ ìpinnu ìsèjọba ti Gómìnà Fayẹmi ńléwájú fún, láti pèsè ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tóyè kóòro fún gbogbo àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ tón bẹ nípinlẹ̀ Èkìtì.

Kò sài sọ́ọ̀di mímọ̀ pe, táwọn ilé-ìwé girama mẹ́rin náà bá parí tán, yóò mágbega bétò ìkẹ́kọ́ọ̀ ọ̀hún.

Nígbà tó ń fèsì, àwọn asojú àwọn agbasẹ́ se náà, wá sèlérí pé, àwọn yóò parí isẹ́ náà kó tódi ìparí osù yíì.

Ogunrinde/Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *