Yoruba

Àwọn onímọ̀ nípa ètò ẹ̀kọ́ gbàjọba níyànjú lórí bétò ẹ̀kọ́ kíkọ́ yo se rọrùn

Àwọn onímọ̀ nípa ètò ẹ̀kọ́ ti sọpé, ó se pàtàkì fún ìjọba láti pèsè àwọn ǹkan amáyédẹrùn èyí tí yóò mú kétò ẹ̀kọ́ kíkọ́ máà ja fafasi lákoko àtilẹyin àrùn covid-19.

Lákokò tíwọ́n ń kópa lórí ètò ilé-isẹ́ Radio Nigeria kan lédè gẹ́ẹ̀si, tapeni Focal point, niwọn fìdí èyí múlẹ̀ nípa yàra ìkàwé, ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ìmọ̀ nípa fifi àkọsílẹ̀ pamọ́, nílé ẹ̀kọ́ gíga fasity ìbàdàn, sàlàyé pé, ìbẹ́sílẹ̀ àrùn covid-19 ti sàkóbá tí kò lẹ́gbẹ́ fẹ́ka ètò ẹ̀kọ́.

Ọkan lára wọn, ọ̀mọ̀wé Adeniyi Akangbe tó gbàjọba níyànjú láti mágbega bá ìmọ̀ ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ fétò ẹ̀kọ́ kíkọ́ sàlàyé pé, ìpèsè àwọn ẹ̀rọ ayárabíasa àtàwọn ohun-èlò rẹ̀, yóò mu kétò ẹ̀kọ́ kíkọ́ jáfáfási.

Nígbà tón náà sọ̀rọ̀, Osarobu Igudia tọ́kasi pé, ó ti wá tó àkókò fún ìjọba láti túbọ̀ gbọnwọ́n sówó tó ń náà sẹ́ka ètò ẹ̀kọ́, lákokò yíì.

Wọ́n wá ké sáwọn òbí láti fọwasowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba fétò ẹ̀kọ́ kíkọ́ tó yè kóòro àtàyíká tó dùn kẹkóò fáwọn akẹ́kọ́ọ̀ lákokò àrùn covid-19 àti lkyìn rẹ̀.

wojuade     

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *