News Yoruba

Ijoba Apapo Gbe Igbimo Kale Lori Ekunwo Owo Ina Oba.

Igbimo kan to ni ninu, awon asoju ile ise ijoba, lajolajo, egbe awon osise NLC, ati TUC ni won ti gbe kale lati sise lori ekunwo owo ina oba bere lati oni yi lo.

 Igbimo yi ni ireti wa wipe yio sise fun ose meji.

Alakoso foro awon osise ati igbani sise nile yi, Ogbeni Chris Ngige lo sore yi nigbati, o nka atejade ipade ti won fi sita leyin ipade lati yanju aawo laarin egbe awon osise ati ijoba to waye nilu Abuja.

O salaye wipe igbimo naa yio sagbeyewo idi ti liana tuntun naa fi se Pataki lojuna ati woo boya idi ti won fi gbe liana tuntun naa kale fesemule.

Alakoso naa ni lori oro to nlo salaye wipe ijoba yio wa ona lati ro owo ori to gun owo osu tuntun gegebi ona lati mu adinku ba ipa ti liana naa ni lori awon omo ile ye.

Nibayi naa, egbe awon osise ti so iyanselodi ti npero re nitori ekunwo owo epo ati ina oba ro fun ose meji.

Adesanya/Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *