Yoruba

NUT bèrè fún ohun amáyédẹrùn fétò ẹ̀kọ́ tóyèkóòro

Ẹwẹ wọ́n ti rọ ìjọba láti pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn tóòyẹ sáwọn ilé-ìwé kétò ẹ̀kọ́ kíkọ́ léè rọrùn.

Alága ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ nílẹ̀ yíì NUT, ẹ̀ka tìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Samson Adedoyin sọ̀rọ̀ yíì lásìkò tó ńbá akọ̀ròyìn ilésẹ́ wa sọ̀rọ̀ lórí àyájọ́ ọjọ́ olùkọ́ fún tọdún yíì.

Alága ẹgbẹ́ NUT, ohun sọpé lóòtọ isẹ́ olùkọ́ ti díì tìgbàlódé, pẹ̀lú àlàyé pé pípèsè àwọn ohun amáyédẹrù ìgbàlóòdé yóò sèrànwọ́ fẹ́ka náà.

Diẹ lára àwọn olùkọ́ tó bá akọ̀ròyìn wa sọ̀rọ̀ rọ ìjọba làti d;akun-dábọ̀ mú ètò ìgbáyégbádùn wọn lọ́kunkún, fún ìjáfáfá ọ̀tun lẹ́nu isẹ́ wọn.

Famakin/idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *