Yoruba

Agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ pèfún mímọrírì àwọn olùkọ́

Bí àgbáyé se ń sàmíì àyájọ́ ọjọ́ àwọn olùkọ́ adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin ti sàpèjúwe àwọn olùkọ́ gẹ́gẹ́ bí igilẹ́yìn ọgbà ìdàgbàsókè àwùjọ tí ó sepàtàkì láti máà mọrírì nígbàgbogbo.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkínni rẹ̀ fún àyájọ́ àwọn olùkọ́ fún tọdún yíì, ọ̀gbẹ́ni Ogundoyin kí àwọn olùkọ́ nílẹ̀ Nàijírìa àti ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ kú oríre, ayẹyẹ ohun èyítí àjọ UNESCO sèdásílẹ̀ rẹ̀ lọ́dún 1994.

Adarí ilé sọpé kòsí ẹni yóòwu tó se àseyọ́rí tí kóò gba iwájú olùkọ́ kọ́ọ̀já, pẹ̀lú àlàyé pé, fífi ọjọ́ kan mọ́ọ̀ rírì wọn sepàtàkì.

kehinde/idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *