Yoruba

Gómìnà Oyetọla fọwọ́sí sísan àjẹlẹ àjẹmọ́nú àwọn òsìsẹ́ fẹ̀yìntì

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọsun, ọ̀gbẹ́ni Adegboyega Oyetọla ti buwọlu yíyọ̀nda owó tóòléní ẹdẹgbẹrin milliọnu naira, láti san owó àjẹmọ́nú àwọn òsìsẹ́ fẹ̀yìntì nípinlẹ̀ náà.

Olórí òsìsẹ́, ọ̀gbẹ́ni Festus Oyebade ẹnitó sọ èyí nílu Òsogbo, sọpé, owótólédiẹ lẹdẹgbẹta milliọnu naira lára owó ohun lójẹ́ bíbuwọ́lù láti san owó àjẹmọ́nú àwọn òsìsẹ́ fẹ̀yìntì tí èyí tókù sìjẹ́ yíyàsọ́tọ̀ láti san owó ìfẹ̀yìntì àwọn òsìsẹ́.

Ọgbẹni Oyebade sàlàyé pé àwọn tí yóò jẹ́ ànfàní ẹ̀tọ́ ohun jẹ́ yíyan níbamu pẹ̀lú ìkojuòsùwọ̀n wọn, toniko wọn siti jẹ lílẹ̀ sójú pátákó ẹ̀ka ìròyìn àti ìlanilọ́ọ̀yẹ̀ nílesẹ́ tó ńrísí ọ̀rọ̀ àwọn òsìsẹ́ fẹ̀yìntì àti ọffisi olórí òsìsẹ́.

Olórí òsìsẹ́ Oyebade wá fikun pé, ìgbésẹ̀ sísan owó náà yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́la òde yíì.

Adenitan Akinola/Elizabeth Idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *