Àjọ ẹ̀sọ́ ojú pópó, FRSC, ti rọ àwọn tó ńsàmúlò ojú òpópónà, láti máà sọ́ráàse lásìkò osù bà-bà-bà láti dènà ìjàmbà ọkọ̀ ikú òjijì àti ìfarapa.

Ọga n’ílesẹ́ náà, lẹ́kùn Èkó àti Ògùn, ọ̀gbẹ́ni Imoh Etuk sọ̀rọ̀ yíì níbi ìfilọ́lẹ̀ ètò ìlanilọ́yẹ̀ osù bà-bà-bà nípinlẹ̀ Èkó.

Ótọkasi pé, óléní èèyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin tó gbẹ́mimì látara ìjàmbá ọkọ̀ lọ́dún 2019, nílẹ̀ Nàijírìa táwọn tóòtóò ẹgbẹrunlọna ọgbọn sì farapa yana-yana.

Ọgbẹni Etuk, dẹ̀bi púpọ̀ nínú àwọn ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ojú pópó ru, eré àsájù, pẹ̀lú àlàyé pé àjọ FRSC, ti setán láti wójùtú sí ìsẹ̀lẹ̀ ọhun èyí tósìmú àjọ náà sàgbékalẹ̀ ẹ̀rọ tó ńsòdiwọ̀n eré sísá.

Kò sài wá rọ àwọn awakọ̀ láti ma sọ́rase lójú pópó lọ́nà àti mádinkù bá ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ojú pópó.

Net/Elizabeth Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *