Yoruba

Gómìnà Seyi Makinde Sèlérí Láti Mú Inú Ẹbí Àwọn Ọlọ́pa Tíwọ́n Sekúpa Nínú Ìfẹ̀húnúhàn Dùn

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ẹ̀rọ Seyi Makinde ti sèlérí pé òun yóò ridájú pé òun dun ẹbí àwọn ọlọ́pa tíwọ́n sekúpa lákokò ìfẹ̀húnúhàn fífòpinsí ikọ̀ SARS, nínú tóun yóò sì sàtúnse sáwọn ilé-isẹ́ ọlọ́pa tíwọ́n bà jẹ́.

Níbi ìpàdé àláfìa kan tí Gómìnà se pẹ̀láwọn ọ̀gá àgbà ilé-isẹ́ ọlọ́pa ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ tó wáyé lólúlesẹ́ náà, ládugbò Ẹlẹ́yẹlé nílu ìbàdàn, ló ti fọwọ́ ìdánilójú náà sọ̀yà.

Nígbà tón se ìbánikẹ́dùn pẹ̀láwọn ọ̀gá ọlọ́pa náà lórí ikú àwọn òsìsẹ́ wọn tólọ, Gómìnà Makinde wá rọ̀wọ́n láti gbàgbé gbogbo àwọn ǹkan tóti sẹlẹ̀ ní ǹkanbi ọ̀sẹ̀ diẹ sẹ́yìn.

Kò sài tún bèèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ọlọ́pa ọ̀hún pẹ̀lú ètò ìsèjọba rẹ̀, tófimọ́ wọn èèyàn min tọ́rọ̀kan lọ́nà àti jẹ́ káwọn èèyàn máà ní nígbàgbọ́ nínú wọn lákokò tíwà bá ń fẹsẹ òfin àti ìlànà múlẹ̀ láwùjọ.

Sáájú nínú ọ̀rọ̀ t’ígbákejì ọ̀gá àgbà pátápátá fọ́rọ̀ ọlọ́pa, tó wà fẹ́kùn ìwọ̀óòrùn gúsù, Ọ̀gbẹ́ni Lẹyẹ Oyebade, késáwọn òsìsẹ́ abẹ́ rẹ̀ nípinlẹ̀ yíì láti sisẹ́ lórí ọ̀rọ̀ tí Gómìnà sọ, kíwọ́n sì ridájú pé àláfìa jọba yíká.

Nínú ọ̀rọ̀ tiwọn náà, alákoko fọ́rọ̀ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Joe Enwonwu àtọ̀gágun àgbà Adesọji ọ̀wọ́ kejì dìjọ rọ àwọn òsìsẹ́ ọlọ́pa láti máà sisẹ́ wọn níbamu pẹ̀lú àsẹ ọ̀gá àgbà pátápátá fọ́rọ̀ ọlọ́pa nílẹ̀ yíì, Ọ̀gbẹ́ni Muhammed Adamu.

Iyabo Adebisi/Folakemi Wojuade    

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *