Àjọ tón bójútó owó ìfẹ̀yìntì àwọn ọmọ ológun, ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sílé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà láti fikun àbá ìsúná wọn kí wọ́n lè sanwó òsìsẹ́ fẹ̀yìntì ilẹ̀ yí lẹ́ka ilésẹ́ ológun.

Alága àjọ ọ̀hún, ọ̀gbẹ́ni Saburi Lawal ló rawọ́ ẹ̀bẹ̀ yí nílu Abuja lásìkò tó wá síwájú ilé.

Gẹ́gẹ́bí alága se wí, àjọ náà ló nísẹ́ láti sanwó ìfẹ̀yìntì fáwọn ológun tó fẹ̀yìntì, sísan ẹ̀tọ́ fún ẹni tó ń sọ́lé de òsìsẹ́ ológun tó ti papòdá, nípasl lílo owó èyí tilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà fọwasí.

Ọgbẹni Lawal sọpé ìsúná ọdọdún yi ni wọ́n pin yẹ́lẹyẹ̀lẹ lórí owó ìfẹ̀yìntì olósosù, àwọn owó náà, miràn fún ìgbáyégbádù àwọn òsìsẹ́ fẹ̀yìntì.

Nígbà tón fèsì alága ìgbìmọ̀ tón mójútó ọ̀rọ̀ tóníse pẹ̀lú owó ìfẹ̀yìntì Aliyu Wammakko sọ pé ìgbìmọ̀ náà yo bójútó àwọn ọ̀rọ̀ tó se kókó, tígbìmọ̀ tón mójútó owó ìfẹ̀yìntì àwọn òsìsẹ́ ológun gbé síwájú fún àfojúsùn.

Ololade Afonja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *