Àdínkù tó dé bá ikú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tọ́jọ́ orí wọn wà lábẹ́ ọdún márun tíwọ́n bí nílẹ̀ Nàijírìa láti ọ̀kànlérúgba tó wà lọ́dún 2003 sí méjìléláadóje lọ́dún 2018, kò tó ǹnkan láti bá àfojúsùn èróngbà ìdàgbàsókè sáà tawàyíì dọ́gba.

Alákoko àjọ tó ń rísọ́rọ̀ beeyan se pọ̀ sí nílẹ̀ Nàijírìa, NPC, ọ̀mọ̀wé Eyitayọ Oyetunji ló sọ̀rọ̀ yíì di mímọ́ níbi ètò ìdánilẹ́kọọ tó wáyé lórí ẹ̀rọ ayélujára, ló dá lórí àbájàde ìwádi lórí ètò kan tayọ náà gbékalẹ̀, tó pèní VASA.

Ètò Vasa yíì làjọ NPC, gbékalẹ̀ láti mọ̀ nípa ohun tó sokunfà ikú àwọn ọmọ tọ́jọ́ orí wọn wà lábẹ́ ọdún márun nílẹ̀ Nàijírìa láárin ọdún 2013 sí 2018.

Gẹ́gẹ́ bí àbájáde Vasa se sọ́ọ̀di mímọ̀, ẹkùn ìwọ́orùn gúsù ill yíì lóní àkọsílẹ̀ iye ọmọ wẹ́wẹ́ tó kú, tó kéré jù tíì se ìdá ogún nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ̀rún kan tíwọ́n bí, nígbà tí àríwá ìwọ́orùn ilẹ̀ Nàijírìa, ní àkọsílẹ̀ tó pọ́jùlọ ní tiẹ, tíì se mẹ́tàdínlọ́gọ́fà.

Ọmọwe Oyetunji ẹni tó tẹnumọ́ ìdí tó fi sepàtàkì fáwọn tó ń sàgbékalẹ̀ ìlànà àtàwọn tọ́rọkàn gbọ̀ngbọ̀n lẹ́ka ètò ìlera fi gbọdọ̀ sisẹ́ lórí mímú àdínkù bá ikú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ sọpé, àbọ̀ ìwádi yíì, yóò sisk gẹ́gẹ́ bí atọ́nà láti sàgbékalẹ̀ ètò tó jáfáfá.

Kò sài tún fikun pé, àkọsílẹ̀ yíì niwọ́n yóò gbékalẹ̀ lọ́nà tí yóò rọrùn láti sàmílò fún gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kàn.

Kẹhinde/Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *