Ìsèjọba ààrẹ Muhammadu Buhari yóò tẹ̀wáwájú ní di mímọ́rọ̀ ìdàgbàsókè ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn lọ́kunkúdùn nípasẹ̀ ètò ìrónilágbára fáwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin tí yóò se kóríyá fún láti fi yan ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn láàyo.

Alága ìgbìmọ̀ níbùdó tón rísísẹ́ ìwádi nípa ọ̀gbìn ewébẹ̀, NIHORT, Ajagun fẹ̀yìntì Garba Muhammed, ló sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ lákokò tó ń síde ètò ìdánilẹ́kọ ọlọ́jọ́ kan lórí ìpèsè ọ̀pẹ̀ òyìnbó fáwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin nílu Ìbàdàn.

 Ọgagun àgbà Muhammed wá sàpèjúwe ìdánilẹ́kọ fáwọn ọ̀dọ́ tí kò nísẹ́ lọ́wọ́ náà, gẹ́gẹ́ bí ara àayan ìjọba àpapọ̀ láti mágbende bá ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀dè yíì.

Sáàjú nínú ọ̀rọ̀ ọ̀gá àgbà ibùdó NIHORT, nílu Ìbàdàn, ọ̀mọ̀wé Abayọmi Ọlaniyan jẹ́jẹ àtìlẹ́yìn ibùdó náà láti pèsè àwọn onímọ̀ tí yóò sisẹ́ papọ̀ pẹ̀láwọn tó jànfàní ètò ìdánilẹ́kọ ọ̀hún, fimu kí ìpèsè ọ̀pẹ̀ òyìnbó tamọ̀sí PineApple rúgọ́gọ́si.

 Mẹ́ta lára àwọn tó jànfàní ètò náà, David Forunso, Ọlaitan Ọlalẹyẹ, àti Dorcas Damilọla gbóríyìn fún ìjọba àpapọ̀, tíwọ́n sì sèlérí pé àwọn yóò sàmúlò ìmọ̀ táwọn ríkọ́ níbi ètò náà dada, táwọn ẹlomin náà yóò sì tún jànfàní látara ìmọ̀ ọ̀hún.

Bí àwọn olùkópa àadọ́ta, nínú èyí tọ́pọ̀ nínú wọn ti jẹ́ ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin ló jànfàní látara ètò ìdánilẹ́kọ ọ̀fẹ́ ọ̀hún lórí ìpèsè ọ̀pẹ̀ òyìnbó.

Kehinde/Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *