Ìjọba orílẹ̀dè Saudi Arabia ti sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, òun yóò fún bi irinwo àwọn akẹ́kọ́ọ̀ ilẹ̀ Nàijírìa létò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, tófimọ́ fífiàyè ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ sílẹ̀ fáwọn akẹ́kọ́ọ̀ ilẹ̀ adúláwọ̀ tó lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́fà lọ́dọọdún.

Èyí ló jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan, tí ilé-isẹ́ asojú ilẹ̀ Saudi Arabia, nílẹ̀ Nàijírìa fi sí ta nílu Abuja, tó sì sàpèjúwe ìgbésẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìbásepọ̀ tógúnmọ́ láàrin orílẹ́dè Saudi Arabia àtilẹ̀ adúláwọ̀ fétò ẹ̀kọ́ àtìdàgbàsókè ìmọ̀ sayẹnsi láti mọ̀ nípa ọ̀nà àti kópa fétò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ọ̀hún, wọ́n ti rọ àwọn akẹ́kọ láti lọ sí ilé-isẹ́ ìjọba tón rí sọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, àtilésẹ́ ìjọba fọ́rọ̀ ẹ̀kọ́ lórílẹ̀dè wọn.

 Aminat/Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *