Yoruba

Àwọn Akẹ́kọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga Nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́ Wọ́de Lórí Ìyansẹ́lódì Ẹgbẹ́ ASUU

Àwọn akẹ́kọ ilé ẹ̀kọ́ gíga nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ lówurọ̀ òní péjọ sílé isẹ́ ìjọba àpapọ̀ láti fẹ̀húnúhàn lórí bí ìyansẹ́lódì ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga ASUU, tise múkí wọn wà nílé fúngbà pípẹ́.

Àwọn akẹ́kọ náà tí wọ́n gbé àkọlé oníruru lọ́wọ́ ni wọ́n dí ẹnu ìloro ilé isẹ́ ọ̀ún.

Akọ̀ròyìn ilé isẹ́ Radio Nigeria jabọ̀ pé, òpópónà tó so agbègbè Custom mọ́ Gate n’ílu Ìbàdàn ni wọ́n gbégi dí.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nu wò, àarẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ ẹ̀ka ti ilé-ẹ̀kọ́ gíga tìlú ìbàdàn, ọ̀gbẹ́ni Olusẹgun Akẹju ní ìwọ́de tí wọ́n se ni ò lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òsèlú kankan tàbí ti ẹgbẹ́ ASUU nínú rárá.

Rotimi Famakin/Yẹmisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *